Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣàyàn ló wà láti ṣe ìwé owó fún àwọn oníbàárà. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìpìlẹ̀ jù lọ ni láti ṣẹ̀dá ìwé nínú ètò ìkọ̀wé kí ẹ sì máa ṣàtúnṣe rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá nílò láti ṣe ìwé owó fún oníbàárà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè gba àkókò, ó túmọ̀ sí pé ẹ lè ní àwọn àyè èyíkéyìí tí ẹ bá fẹ́ lórí ìwé owó yín.
Àṣàyàn míràn ni ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣàfilọ́lẹ̀ tàbí sọ́fítíwià tí ó lè ṣẹ̀dá ìwé owó fúnra rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìṣàfilọ́lẹ̀ fóònù alágbèéká ló wà báyìí tí ó lè ṣẹ̀dá ìwé owó kí ó sì fi ímeèlì ránṣẹ́ sí àwọn oníbàárà yín, ẹ sì lè fi gbogbo àlàyé àwọn oníbàárà pamọ́ kí ẹ má bàa máa ṣe èyí ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá ṣẹ̀dá ìwé owó.
Àwọn àsọyé
Kò tíì sí àsọyé kankan.